Awikonko Television

Orírun Wa Ń Ilé - Ife - T''eni N T''eni Ekisa Lo L'aatan! Elenu Rirun Lo L'amu Iya E! On'isu Nje'su,E Lo S'enu Yankan-Yankan; At'isu,At'enu Se B'oun Lo Ni Nkan E. Iran Yoruba Lo Ni 'EWA EDE' Ninu ASA YORUBA. L'ori Ikanni Yii 'EWA EDE YORUBATV' E O Maa L'anfaani Si Olokan O Jo'kan Ohun Enu YORUBA Bii AYOKA OLOYIN, ONKA YORUBA ,ORIKI, ITAN, EDE ATI ASA YORUBA To Jiire. Pelu Ọlọ́kan Ò Jọ̀'kan Ètò. Ede Ati Asa YORUBA O Ni i Parun. Agbajowo La Fi Nso'ya,Ajeje Owo Kan O Gbe'gba D'ori. Ijo Ajumo Jo Ni i Gbayi,Ijo Anikan Jo Ni i Ko'ni L'ese. Osusu Owo Lo Le Gba'le Mo. Opo Esu Ni i Ya'gi L'oko. Opo Giiri Ese Ni i Ye'na. Opo Ikan Ni i Mo'le,Opo Oyin Ni i S'afara.Opo Eerun A Si M'agiyan. E Je Ka So'wo Po Gbe Ede Ati Asa YORUBA L'aruge! A a Ju Wa a Se o!